8 Baraki si wi fun u pe, Bi iwọ o ba bá mi lọ, njẹ emi o lọ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba bá mi lọ, emi ki yio lọ.
9 On si wipe, Ni lilọ emi o bá ọ lọ: ṣugbọn ọlá ọ̀na ti iwọ nlọ nì ki yio jẹ́ tirẹ; nitoriti OLUWA yio tà Sisera si ọwọ́ obinrin. Debora si dide, o si bá Baraki lọ si Kedeṣi.
10 Baraki si pè Sebuluni ati Naftali si Kedeṣi; on si lọ pẹlu ẹgba marun ọkunrin lẹhin rẹ̀: Debora si gòke lọ pẹlu rẹ̀.
11 Njẹ Heberi ọmọ Keni, ti yà ara rẹ̀ kuro lọdọ awọn ọmọ Keni, ani awọn ọmọ Hobabu, ana Mose, o si pa agọ́ rẹ̀ titi dé igi-oaku Saanannimu, ti o wà li àgbegbe Kedeṣi.
12 Nwọn si sọ fun Sisera pe, Baraki ọmọ Abinoamu ti lọ si òke Tabori.
13 Sisera si kó gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ jọ, ẹdẹgbẹrun kẹkẹ́ irin, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, lati Haroṣeti awọn orilẹ-ède wá si odò Kiṣoni.
14 Debora si wi fun Baraki pe, Dide; nitoripe oni li ọjọ́ ti OLUWA fi Sisera lé ọ lọwọ: OLUWA kò ha ti ṣaju rẹ lọ bi? Bẹ̃ni Baraki sọkalẹ lati òke Tabori lọ, ẹgba marun ọkunrin si tẹle e lẹhin.