1 NIGBANA ni Debora on Baraki ọmọ Abinoamu kọrin li ọjọ́ na, wipe,
2 Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA.
3 Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli.
4 OLUWA, nigbati iwọ jade kuro ni Seiri, nigbati iwọ nyan jade lati pápa Edomu wá, ilẹ mìtiti, awọn ọrun si kánsilẹ, ani awọsanma pẹlu kán omi silẹ.
5 Awọn òke nla yọ́ niwaju OLUWA, ani Sinai yọ́ niwaju OLUWA; Ọlọrun Israeli.
6 Li ọjọ́ Ṣamgari ọmọ Anati, li ọjọ́ Jaeli, awọn ọ̀na opópo da, awọn èro si nrìn li ọ̀na ìkọ̀kọ̀.