15 Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
16 Ẽṣe ti iwọ fi joko lãrin agbo-agutan lati ma gbọ́ fere oluṣọ-agutan? Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
17 Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀.
18 Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa.
19 Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo.
20 Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara.