20 Nwọn jà lati ọrun wá, awọn irawọ ni ipa wọn bá Sisera jà.
21 Odò Kiṣoni gbá wọn lọ, odò igbani, odò Kiṣoni. Hã ọkàn mi, ma yan lọ ninu agbara.
22 Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn.
23 Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara.
24 Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́.
25 O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye.
26 O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin.