22 Nigbana ni patako ẹsẹ̀ ẹṣin kì ilẹ, nitori ire-sisá, iré-sisá awọn alagbara wọn.
23 Ẹ fi Merosi bú, bẹ̃li angeli OLUWA wi, ẹ fi awọn ara inu rẹ̀ bú ibú kikorò; nitoriti nwọn kò wá si iranlọwọ OLUWA, si iranlọwọ OLUWA si awọn alagbara.
24 Ibukún ni fun Jaeli aya Heberi ọmọ Keni jù awọn obinrin lọ, ibukún ni fun u jù awọn obinrin lọ ninu agọ́.
25 O bère omi, o fun u ni warà; o mu ori-amọ tọ̀ ọ wá ninu awo iyebiye.
26 O nà ọwọ́ rẹ̀ mú iṣo, ati ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú òlu awọn ọlọnà; òlu na li o si fi lù Sisera, o gba mọ́ ọ li ori, o si gún o si kàn ẹbati rẹ̀ mọlẹ ṣinṣin.
27 Li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu, o dubulẹ: li ẹsẹ̀ rẹ̀ o wolẹ, o ṣubu: ni ibi ti o gbè wolẹ, nibẹ̀ na li o ṣubu kú.
28 Iya Sisera nwò oju-ferese, o si kigbe, o kigbe li oju-ferese ọlọnà pe; Ẽṣe ti kẹkẹ́ rẹ̀ fi pẹ bẹ̃ lati dé? Ẽṣe ti ẹsẹ̀ kẹkẹ̀ rẹ̀ fi duro lẹhin?