A. Oni 6:25-31 YCE

25 O si ṣe li oru ọjọ́ kanna, li OLUWA wi fun u pe, Mú akọ-malu baba rẹ, ani akọ-malu keji ọlọdún meje, ki o si wó pẹpẹ Baali ti baba rẹ ní lulẹ ki o si bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ:

26 Ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ lori ibi agbara yi, bi o ti yẹ, ki o si mú akọ-malu keji, ki o si fi igi-oriṣa ti iwọ bẹ́ lulẹ ru ẹbọ sisun.

27 Nigbana ni Gideoni mú ọkunrin mẹwa ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, o si ṣe bi OLUWA ti sọ fun u: o si ṣe, nitoripe o bẹ̀ru ile baba rẹ̀ ati awọn ọkunrin ilu na, tobẹ̃ ti kò fi le ṣe e li ọsán, ti o si fi ṣe e li oru.

28 Nigbati awọn ọkunrin ilu na si dide ni kùtukutu, si wò o, a ti wó pẹpẹ Baali lulẹ, a si bẹ́ igi-oriṣa lulẹ ti o wà lẹba rẹ̀, a si ti pa akọ-malu keji rubọ lori pẹpẹ ti a mọ.

29 Nwọn si sọ fun ara wọn pe, Tali o ṣe nkan yi? Nigbati nwọn tọ̀sẹ̀, ti nwọn si bère, nwọn si wipe, Gideoni ọmọ Joaṣi li o ṣe nkan yi.

30 Nigbana li awọn ọkunrin ilu na wi fun Joaṣi pe, Mú ọmọ rẹ jade wá ki o le kú: nitoripe o wó pẹpẹ Baali lulẹ, ati nitoriti o bẹ́ igi-oriṣa ti o wà lẹba rẹ̀ lulẹ.

31 Joaṣi si wi fun gbogbo awọn ti o duro tì i pe, Ẹnyin o gbèja Baali bi? tabi ẹnyin o gbà a là bi? ẹniti o ba ngbèja rẹ̀, ẹ jẹ ki a lù oluwarẹ̀ pa ni kùtukutu owurọ yi: bi on ba ṣe ọlọrun, ẹ jẹ ki o gbèja ara rẹ̀, nitoriti ẹnikan wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ.