8 OLUWA si rán wolĩ kan si awọn ọmọ Israeli: ẹniti o wi fun wọn pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Emi mú nyin gòke ti Egipti wá, mo si mú nyin jade kuro li oko-ẹrú;
9 Emi si gbà nyin li ọwọ́ awọn ara Egipti, ati li ọwọ́ gbogbo awọn ti npọ́n nyin loju, mo si lé wọn kuro niwaju nyin, mo si fi ilẹ wọn fun nyin;
10 Mo si wi fun nyin pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin; ẹ máṣe bẹ̀ru oriṣa awọn Amori, ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn ẹnyin kò gbà ohùn mi gbọ́.
11 Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani.
12 Angeli OLUWA na si farahàn a, o si wi fun u pe, OLUWA wà pẹlu rẹ, iwọ ọkunrin alagbara.
13 Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ.
14 OLUWA si wò o, o si wipe, Lọ ninu agbara rẹ yi, ki iwọ ki ó si gbà Israeli là kuro lọwọ Midiani: Emi kọ ha rán ọ bi?