A. Oni 7:1-7 YCE

1 NIGBANA ni Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, ati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu rẹ̀, dide ni kùtukutu, nwọn si dó lẹba orisun Harodu: ibudó Midiani si wà ni ìha ariwa wọn, nibi òke More, li afonifoji.

2 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia ti o wà lọdọ rẹ pọ̀ju fun mi lati fi awọn Midiani lé wọn lọwọ, ki Israeli ki o má ba gbé ara wọn ga si mi, pe, Ọwọ́ mi li o gbà mi là.

3 Njẹ nitorina, lọ kede li etí awọn enia na, wipe, Ẹnikẹni ti o ba nfòya ti ẹ̀ru ba si mbà, ki o pada lati òke Gileadi ki o si lọ. Ẹgbã mọkanla si pada ninu awọn enia na; awọn ti o kù si jẹ́ ẹgba marun.

4 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Awọn enia na pọ̀ju sibẹ̀; mú wọn sọkalẹ wá si odò, nibẹ̀ li emi o gbé dan wọn wò fun ọ: yio si ṣe, ẹniti mo ba wi fun ọ pe, Eyi ni yio bá ọ lọ, on na ni yio bá ọ lọ; ẹnikẹni ti mo ba si wi fun ọ pe, Eyi ki yio bá ọ lọ, on na ni ki yio si bá ọ lọ.

5 Bẹ̃li o mú awọn enia na wá si odò: OLUWA si wi fun Gideoni pe, Olukuluku ẹniti o ba fi ahọn rẹ̀ lá omi, bi ajá ti ma lá omi, on na ni ki iwọ ki o fi si apakan fun ara rẹ̀; bẹ̃ si li olukuluku ẹniti o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ lati mu omi.

6 Iye awọn ẹniti o lá omi, ti nwọn fi ọwọ́ wọn si ẹnu wọn, jẹ́ ọdunrun ọkunrin: ṣugbọn gbogbo awọn enia iyokù kunlẹ li ẽkun wọn lati mu omi.

7 OLUWA si wi fun Gideoni pe, Nipaṣe ọdunrun ọkunrin wọnyi ti o lá omi li emi o gbà nyin, emi o si fi awọn Midiani lé ọ lọwọ: jẹ ki gbogbo awọn iyokù lọ olukuluku si ipò rẹ̀.