12 Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ.
13 Nigbati Gideoni si dé, kiyesi i, ọkunrin kan nrọ́ alá fun ẹnikeji rẹ̀, o si wipe, Kiyesi i, emi lá alá kan, si wò o, àkara ọkà-barle kan ṣubu si ibudó Midiani, o si bọ́ sinu agọ́ kan, o si kọlù u tobẹ̃ ti o fi ṣubu, o si doju rẹ̀ de, agọ́ na si ṣubu.
14 Ekeji rẹ̀ si da a lohùn, wipe, Eyiyi ki iṣe ohun miran bikoṣe idà Gideoni ọmọ Joaṣi, ọkunrin kan ni Israeli: nitoripe Ọlọrun ti fi Midiani ati gbogbo ibudo lé e lọwọ.
15 O si ṣe, nigbati Gideoni gbọ́ rirọ́ alá na, ati itumọ̀ rẹ̀, o tẹriba; o si pada si ibudó Israeli, o si wipe, Ẹ dide; nitoriti OLUWA ti fi ogun Midiani lé nyin lọwọ.
16 On si pín ọdunrun ọkunrin na si ẹgbẹ mẹta, o si fi ipè lé olukuluku wọn lọwọ, pẹlu ìṣa ofo, òtufu si wà ninu awọn ìṣa na.
17 On si wi fun wọn pe, Ẹ wò mi, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ: si kiyesi i, nigbati mo ba dé opin ibudó na, yio si ṣe bi emi ba ti ṣe, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe.
18 Nigbati mo ba fun ìpe, emi ati gbogbo awọn ti mbẹ lọdọ mi, nigbana ni ki ẹnyin pẹlu ki o fun ìpe yiká gbogbo ibudó na, ki ẹnyin ki o si wi pe, Fun OLUWA, ati fun Gideoni.