22 Awọn ọkunrin na fun ọdunrun ipè, OLUWA si yí idà olukuluku si ẹnikeji rẹ̀, ati si gbogbo ogun na: ogun na si sá titi dé Beti-ṣita ni ìha Serera, dé àgbegbe Abeli-mehola, leti Tabati.
23 Awọn ọkunrin Israeli si kó ara wọn jọ lati Naftali, ati lati Aṣeri ati lati gbogbo Manasse wá, nwọn si lepa awọn Midiani.
24 Gideoni si rán onṣẹ lọ si gbogbo òke Efraimu, wipe, Ẹ sọkalẹ wá pade awọn Midiani, ki ẹ si tète gbà omi wọnni dé Beti-bara ani Jordani. Nigbana ni gbogbo awọn ọkunrin Efraimu kó ara wọn jọ, nwọn si gbà omi wọnni, titi dé Beti-bara ani Jordani.
25 Nwọn si mú meji ninu awọn ọmọ-alade Midiani, Orebu ati Seebu; Orebu ni nwọn si pa lori apata Orebu, ati Seebu ni nwọn si pa ni ibi-ifọnti Seebu, nwọn si lepa awọn ara Midiani, nwọn si mú ori Orebu ati Seebu wá fi fun Gideoni li apa keji odò Jordani.