25 Nwọn si dahùn wipe, Tinutinu li awa o fi mú wọn wá. Nwọn si tẹ́ aṣọ kan, olukuluku nwọn si sọ oruka-etí ikogun rẹ̀ si i.
26 Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn.
27 Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀.
28 Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.
29 Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀.
30 Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀.
31 Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki.