4 Gideoni si dé odò Jordani, o si rekọja, on ati ọdunrun ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀, o di ãrẹ, ṣugbọn nwọn nlepa sibẹ̀.
5 On si wi fun awọn ọkunrin Sukkotu pe, Emi bẹ̀ nyin, ẹ fi ìṣu-àkara melokan fun awọn enia wọnyi ti ntọ̀ mi lẹhin: nitoriti o di ãrẹ fun wọn, emi si nlepa Seba ati Salmunna, awọn ọba Midiani.
6 Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ?
7 Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin.
8 On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn.
9 On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀.
10 Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu.