6 Awọn ọmọ-alade Sukkotu si wi pe, ọwọ́ rẹ ha ti ítẹ Seba on Salmunna na, ti awa o fi fun awọn ogun rẹ li onjẹ?
7 Gideoni si wipe, Nitorina nigbati OLUWA ba fi Seba ati Salmunna lé mi lọwọ, nigbana li emi o fi ẹgún ijù, ati oṣuṣu yà ẹran ara nyin.
8 On si gòke lati ibẹ̀ lọ si Penueli, o si sọ fun wọn bẹ̃ gẹgẹ: awọn ọkunrin Penueli si da a lohùn gẹgẹ bi awọn ara Sukkotu si ti da a lohùn.
9 On si wi fun awọn ọkunrin Penueli pẹlu pe, Nigbati mo ba pada dé li alafia, emi o wó ile-ẹṣọ́ yi lulẹ̀.
10 Njẹ Seba ati Salmunna wà ni Karkori, ogun wọn si wà pẹlu wọn, o to ìwọn ẹdẹgbajọ ọkunrin, iye awọn ti o kù ninu gbogbo ogun awọn ọmọ ìha ìla-õrùn: nitoripe ẹgba ọgọta ọkunrin ti o lo idà ti ṣubu.
11 Gideoni si gbà ọ̀na awọn ti ngbé inú agọ́ ni ìha ìla-õrùn Noba ati Jogbeha gòke lọ, o si kọlù ogun na; nitoriti ogun na ti sọranù.
12 Seba ati Salmunna si sá; on si lepa wọn; o si mù awọn ọba Midiani mejeji na, Seba ati Salmunna, o si damu gbogbo ogun na.