1 Ẹ gbọ̀ ọ̀rọ yi ti Oluwa ti sọ si nyin, ẹnyin ọmọ Israeli, si gbogbo idile ti mo mú goke lati ilẹ Egipti wá, wipe,
2 Ẹnyin nikan ni mo mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina emi o bẹ̀ nyin wò nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin.
3 Ẹni meji lè rìn pọ̀, bikòṣepe nwọn rẹ́?
4 Kiniun yio ké ramùramù ninu igbo, bi kò ni ohun ọdẹ? ọmọ kiniun yio ha ké jade ninu ihò rẹ̀, bi kò ri nkan mu?
5 Ẹiyẹ le lu okùn ni ilẹ, nibiti okùn didẹ kò gbe si fun u? okùn ha le ré kuro lori ilẹ, laijẹ pe o mu nkan rara?
6 A le fun ipè ni ilu, ki awọn enia má bẹ̀ru? tulasi ha le wà ni ilu, ki o má ṣepe Oluwa li o ṣe e?