11 Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.
12 Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn.
13 Nitorina ẹni-oye yio dakẹ nigbana; nitori akòko ibi ni.
14 Ẹ ma wá ire, kì isi iṣe ibi, ki ẹ ba le yè; bẹ̃ni Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, yio si pẹlu nyin, bi ẹnyin ti wi.
15 Ẹ korira ibi, ẹ si fẹ́ ire, ki ẹ si fi idajọ gunlẹ ni bodè; boya Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun yio ṣe ojurere si iyokù Josefu.
16 Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.
17 Ati ni gbogbo ọ̀gba àjara ni isọkún yio gbe wà: nitori emi o kọja lãrin rẹ, li Oluwa wi.