19 Gẹgẹ bi enia ti o sa fun kiniun, ti beari si pade rẹ̀; tabi ti o wọ̀ inu ile, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ tì lara ogiri, ti ejò si bù u jẹ.
20 Ọjọ Oluwa kì o ha ṣe òkunkun laiṣe imọlẹ? ani òkunkun biribiri, laisi imọlẹ ninu rẹ̀?
21 Mo korira, mo si kẹgàn ọjọ asè nyin, emi kì o si gbõrùn ọjọ ajọ ọ̀wọ nyin.
22 Bi ẹnyin tilẹ rú ẹbọ sisun ati ẹbọ jijẹ nyin si mi, emi kì o si gbà wọn: bẹ̃ni emi ki yio nani ẹbọ ọpẹ́ ẹran abọ́pa nyin.
23 Mu ariwo orin rẹ kuro lọdọ mi; nitori emi kì o gbọ́ iró adùn fioli rẹ.
24 Ṣugbọn jẹ ki idajọ ki o ṣàn silẹ bi omi, ati ododo bi iṣàn omi nla.
25 Ẹnyin ha ti rubọ si mi, ẹ ha ti ta mi lọrẹ li aginjù li ogoji ọdun, ẹnyin ile Israeli.