4 Nitori bayi li Oluwa wi fun ile Israeli, ẹ wá mi, ẹnyin o si yè:
5 Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan.
6 Ẹ wá Oluwa, ẹnyin o si yè; ki o má ba gbilẹ bi iná ni ile Josefu, a si jó o run, ti kì o fi si ẹnikan lati pá a ni Beteli.
7 Ẹnyin ti ẹ sọ idajọ di iwọ, ti ẹ si kọ̀ ododo silẹ li aiye.
8 Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀:
9 Ti o mu iparun kọ manà sori alagbara, tobẹ̃ ti iparun yio wá si odi agbara.
10 Nwọn korira ẹniti nbaniwi li ẹnu bodè, nwọn si korira ẹniti nsọ otitọ.