1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi; si wò o, o dá ẽṣú ni ibẹ̀rẹ irú-soke idàgba ikẹhin, si wò o, idàgba ikẹhìn lẹhìn ike-kuro ti ọba nì.
2 O si ṣe, ti nwọn jẹ koriko ilẹ na tan, nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, darijì, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on.
3 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Kì yio ṣe, li Oluwa wi.
4 Bayi li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si wò o, Oluwa Ọlọrun pè lati fi iná jà, o si jó ibú nla nì run, o si jẹ apakan run.
5 Nigbana ni mo wipe, Oluwa Ọlọrun, dawọ duro, emi bẹ̀ ọ: Jakobu yio ha ṣe le dide? nitori ẹnikekere li on.
6 Oluwa ronupiwàda nitori eyi: Eyi pẹlu kì yio ṣe, li Oluwa Ọlọrun wi.