1 BAYI li Oluwa Ọlọrun ti fi hàn mi: si kiyesi i, agbọ̀n eso ẹrùn kan.
2 On si wipe, Amosi, kili ohun ti iwọ ri? Emi si wipe, Agbọ̀n eso ẹrùn ni. Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Opin de si Israeli enia mi; emi kì yio tún kọja lọdọ wọn mọ.
3 Orin inu tempeli yio si jẹ hihu li ọjọ na, li Oluwa Ọlọrun wi: okú pupọ̀ ni yio wà ni ibi gbogbo; nwọn o ma fi idakẹ jù wọn sode.
4 Ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin ti ngbe awọn alaini mì, lati sọ awọn talakà ilẹ na di alaini,
5 Ti nwipe, Nigbawo ni oṣù titún yio pari, ki awa ba le ta ọkà? ati ọjọ isimi, ki awa ba le ṣi alikama silẹ, ki a si ṣe ìwọn efà kere, ati ìwọn ṣekeli tobi, ki a si ma fi ẹ̀tan yi ìwọn padà?
6 Ki awa le fi fàdakà rà talakà, ati bàta ẹsẹ̀ mejeji rà alaini, ki a si tà eyiti o dànu ninu alikama?
7 Oluwa ti bura nipa ọlanla Jakobu pe, Nitõtọ emi kì yio gbàgbe ọkan ninu iṣẹ wọn.