1 MO ri Oluwa o duro lori pẹpẹ: o si wipe, Lù itẹrigbà ilẹ̀kun, ki awọn òpo ki o le mì: si ṣá wọn li ori, gbogbo wọn; emi o si fi idà pa ẹni ikẹhìn wọn: ẹniti o sá ninu wọn, kì yio salọ gbe; ati ẹniti o sa asalà ninu wọn li a kì yio gbàla.
2 Bi nwọn tilẹ wà ilẹ lọ si ọrun-apadi, lati ibẹ̀ li ọwọ́ mi yio ti tẹ̀ wọn; bi nwọn tilẹ gùn okè ọrun lọ; lati ibẹ̀ li emi o ti mu wọn sọ̀kalẹ:
3 Ati bi nwọn tilẹ fi ara wọn pamọ li ori oke Karmeli; emi o wá wọn ri, emi o si mu wọn kuro nibẹ̀; ati bi a tilẹ fi wọn pamọ kuro niwaju mi ni isàlẹ okun; lati ibẹ̀ na li emi o ti paṣẹ fun ejò nì, on o si bù wọn jẹ:
4 Ati bi nwọn tilẹ lọ si igbèkun niwaju awọn ọta wọn, lati ibẹ̀ wá li emi o ti paṣẹ fun idà, on o si pa wọn: emi a si tẹ̀ oju mi mọ wọn lara fun ibi, kì isi ṣe fun ire.
5 Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun li ẹniti o si fi ọwọ́ kan ilẹ na, yio si di yiyọ́, gbogbo awọn ti o ngbe inu rẹ̀ yio si ṣọ̀fọ: yio si rú soke patapata bi kikun omi: a o si tẹ̀ ẹ ri, bi odò Egipti.