10 Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i.
11 Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ.
12 Ibukún ni fun ẹniti o duro dè, ti o si de ẹgbẹrun, ati ọdurun le marundilogoji ọjọ nì.
13 Ṣugbọn iwọ ma ba ọ̀na rẹ lọ, titi opin yio fi de, iwọ o si simi, iwọ o si dide duro ni ipo rẹ ni ikẹhin ọjọ.