Dan 3:22-28 YCE

22 Nitorina bi aṣẹ ọba ti le to, ati bi ileru na si ti gboná gidigidi to, ọwọ iná na si pa awọn ọkunrin ti o gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, lọ.

23 Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo.

24 Nigbana ni Nebukadnessari ọba warìri o si dide duro lọgan, o dahùn, o si wi fun awọn ìgbimọ rẹ̀ pe, awọn ọkunrin mẹta kọ a gbé sọ si ãrin iná ni didè? Nwọn si dahùn wi fun ọba pe, Lõtọ ni ọba.

25 O si dahùn wipe, Wò o, mo ri ọkunrin mẹrin ni titu, nwọn sì nrin lãrin iná, nwọn kò si farapa, ìrisi ẹnikẹrin si dabi ti Ọmọ Ọlọrun.

26 Nigbana ni Nebukadnessari sunmọ ẹnu-ọ̀na ileru na o dahùn o si wipe, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹnyin iranṣẹ Ọlọrun Ọga-ogo, ẹ jade ki ẹ si wá. Nigbana ni Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, jade lati ãrin iná na wá.

27 Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn.

28 Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn.