Dan 9:10-16 YCE

10 Bẹ̃li awa kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, lati ma rìn nipa ofin ti o gbé kalẹ niwaju wa lati ọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli wá.

11 Bẹ̃ni gbogbo Israeli ti ṣẹ̀ si ofin rẹ, ani nipa kikuro, ki nwọn ki o máṣe gbà ohùn rẹ gbọ́; nitorina li a ṣe yi egún dà si ori wa, ati ibura na ti a kọ sinu ofin Mose, iranṣẹ Ọlọrun, nitori ti awa ti ṣẹ̀ si i.

12 On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu.

13 Gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu ofin Mose, gbogbo ibi wọnyi wá sori wa: bẹ̃li awa kò si wá ojurere niwaju Oluwa, Ọlọrun wa, ki awa ki o le yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa, ki a si moye otitọ rẹ.

14 Nitorina li Oluwa ṣe fiyesi ibi na, ti o si mu u wá sori wa; nitoripe olododo li Oluwa Ọlọrun wa ni gbogbo iṣẹ rẹ̀ ti o nṣe: ṣugbọn awa kò gbà ohùn rẹ̀ gbọ́.

15 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, iwọ ti o ti fi ọwọ agbara mu awọn enia rẹ jade lati Egipti wá, ti iwọ si ti gba orukọ fun ara rẹ gẹgẹ bi o ti wà loni: awa ti ṣẹ̀, awa si ti ṣe buburu gidigidi.

16 Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo ododo rẹ, lõtọ, jẹ ki ibinu ati irunu rẹ yi kuro lori Jerusalemu, ilu rẹ, òke mimọ́ rẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wa, ati ẹ̀ṣẹ awọn baba wa ni Jerusalemu, ati awọn enia rẹ fi di ẹ̀gan si gbogbo awọn ti o yi wa ka.