16 Ṣugbọn awọn ọmọ igbekun ṣe bẹ̃. Ati Esra, alufa, pẹlu awọn olori ninu awọn baba, nipa ile baba wọn, ati gbogbo wọn nipa orukọ wọn li a yà si ọ̀tọ, ti nwọn si joko li ọjọ kini oṣu kẹwa, lati wadi ọ̀ran na.
17 Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini.
18 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah.
19 Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn.
20 Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah.
21 Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah.
22 Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa.