1 NJẸ lẹhin nkan wọnyi, ni ijọba Artasasta ọba Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah,
2 Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu,
3 Ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraiotu,
4 Ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki,
5 Ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olori alufa:
6 Esra yi li o gòke lati Babiloni wá; o si jẹ ayáwọ́-akọwe ninu ofin Mose, ti Oluwa Ọlọrun Israeli fi fun ni: ọba si fun u li ohun gbogbo ti o bère, gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ti wà lara rẹ̀.
7 Ati ninu awọn ọmọ Israeli, ati ninu awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, pẹlu awọn Netinimu si goke wá si Jerusalemu li ọdun keje Artasasta ọba.
8 On si wá si Jerusalemu li oṣu karun, eyi ni ọdun keje ọba.
9 Nitoripe lati ọjọ kini oṣu ekini li o bẹrẹ si igòke lati Babiloni wá, ati li ọjọ ikini oṣu karun li o de Jerusalemu, gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun rẹ̀ ti o wà lara rẹ̀.
10 Nitori Esra ti mura tan li ọkàn rẹ̀ lati ma wá ofin Oluwa, ati lati ṣe e, ati lati ma kọ́ni li ofin ati idajọ ni Israeli.
11 Eyi si ni atunkọ iwe na ti Artasasta ọba fi fun Esra alufa, akọwe, ani akọwe ọ̀rọ ofin Oluwa, ati ti aṣẹ rẹ̀ fun Israeli.
12 Artasasta, ọba awọn ọba, si Esra alufa, akọwe pipé ti ofin Ọlọrun ọrun, alafia:
13 Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ.
14 Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ;
15 Ati lati ko fàdaka ati wura, ti ọba ati awọn ìgbimọ fi tinutinu fi fun Ọlọrun Israeli, ibugbe ẹniti o wà ni Jerusalemu.
16 Ati gbogbo fàdaka ati wura ti iwọ le ri ni gbogbo igberiko Babiloni, pẹlu ọrẹ atinuwa awọn enia, ati ti awọn alufa, ti iṣe ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun wọn ti o wà ni Jerusalemu.
17 Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.
18 Ati ohunkohun ti o ba wu ọ, ati awọn arakunrin rẹ lati fi fàdaka ati wura iyokù ṣe, eyini ni ki ẹnyin ki o ṣe gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nyin.
19 Ohun-èlo wọnni ti a fi fun ọ pẹlu fun ìsin ile Ọlọrun rẹ, ni ki iwọ ki o fi lelẹ niwaju Ọlọrun ni Jerusalemu.
20 Ati ohunkohun ti a ba fẹ pẹlu fun ile Ọlọrun rẹ, ti iwọ o ri àye lati nawo rẹ̀, nawo rẹ̀ lati inu ile iṣura ọba wá.
21 Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara,
22 Titi de ọgọrun talenti fàdaka, ati de ọgọrun oṣuwọn alikama, ati de ọgọrun bati ọti-waini, ati de ọgọrun bati ororo, ati iyọ laini iye.
23 Ohunkohun ti Ọlọrun ọrun palaṣẹ, ki a fi otitọ ṣe e fun ile Ọlọrun ọrun: ki ibinu ki o má de si ijọba ọba, ati awọn ọmọ rẹ̀.
24 Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin kò ni oyè lati di owo-ori, owo-odè, ati owo-bodè ru gbogbo awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, awọn akọrin, awọn adèna, awọn Netinimu, ati awọn iranṣẹ ninu ile Ọlọrun yi,
25 Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn.
26 Ẹnikẹni ti kì o si ṣe ofin Ọlọrun rẹ, ati ofin ọba, ki a mu idajọ ṣe si i lara li aijafara, bi o ṣe si ikú ni, tabi lilé si oko, tabi kiko li ẹrù, tabi si sisọ sinu tubu.
27 Olubukun li Oluwa Ọlọrun awọn baba wa, ti o fi nkan bi iru eyi si ọkàn ọba, lati ṣe ogo si ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu:
28 Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.