Esr 2 YCE

Àwọn tí Wọ́n Pada ti Ìgbèkùn Dé

1 WỌNYI li awọn ọmọ igberiko Juda ti o goke wa, lati inu igbèkun awọn ti a ti ko lọ, ti Nebukadnessari, ọba Babiloni, ti ko lọ si Babiloni, ti nwọn si pada wá si Jerusalemu ati Juda, olukuluku si ilu rẹ̀:

2 Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli:

3 Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn.

4 Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn.

5 Awọn ọmọ Ara, ẹgbẹrin o din mẹ̃dọgbọn.

6 Awọn ọmọ Pahati-Moabu ninu awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejila.

7 Awọn ọmọ Elamu, adọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.

8 Awọn ọmọ Sattu, ọtadilẹgbẹ̀run, o le marun.

9 Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.

10 Awọn ọmọ Bani, ojilelẹgbẹta, o le meji.

11 Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mẹtalelogun.

12 Awọn ọmọ Asgadi, ẹgbẹfa, o le mejilelogun.

13 Awọn ọmọ Adonikami ọtalelẹgbẹta o le mẹfa.

14 Awọn ọmọ Bigfai, ẹgbã o le mẹrindilọgọta.

15 Awọn ọmọ Adini, adọtalenirinwo o le mẹrin.

16 Awọn ọmọ Ateri ti Hesekiah, mejidilọgọrun.

17 Awọn ọmọ Besai, ọrindinirinwo o le mẹta.

18 Awọn ọmọ Jora, mejilelãdọfa.

19 Awọn ọmọ Haṣumu igba o le mẹtalelogun.

20 Awọn ọmọ Gibbari, marundilọgọrun.

21 Awọn ọmọ Betlehemu, mẹtalelọgọfa.

22 Awọn enia Netofa, mẹrindilọgọta.

23 Awọn enia Anatotu, mejidilãdọje.

24 Awọn ọmọ Asmafeti, mejilelogoji.

25 Awọn ọmọ Kirjat-arimu, Kefira ati Beeroti ọtadilẹgbẹrin o le mẹta.

26 Awọn ọmọ Rama ati Gaba, ẹgbẹta o le mọkanlelogun.

27 Awọn ọmọ Mikmasi, mejilelọgọfa.

28 Awọn enia Beteli ati Ai, igba o le mẹtalelogun.

29 Awọn ọmọ Nebo, mejilelãdọta.

30 Awọn ọmọ Magbiṣi mẹrindilọgọjọ.

31 Awọn ọmọ Elamu ekeji, ãdọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.

32 Awọn ọmọ Harimu, ọrindinirinwo.

33 Awọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono, ọrindilẹgbẹrin o le marun,

34 Awọn ọmọ Jeriko, ọtadinirinwo o le marun.

35 Awọn ọmọ Sanaa, egbejidilogun o le ọgbọn.

36 Awọn alufa; awọn ọmọ Jedaiah, ti idile Jeṣua, ogúndilẹgbẹrun o din meje.

37 Awọn ọmọ Immeri, ãdọtalelẹgbẹrun o le meji.

38 Awọn ọmọ Paṣuri, ojilelẹgbẹfa o le meje.

39 Awọn ọmọ Harimu, ẹgbẹrun o le mẹtadilogun.

40 Awọn ọmọ Lefi: awọn ọmọ Jeṣua ati Kadmieli ti awọn ọmọ Hodafiah, mẹrinlelãdọrin.

41 Awọn akọrin: awọn ọmọ Asafu, mejidilãdoje.

42 Awọn ọmọ awọn adena: awọn ọmọ Ṣalumu, awọn ọmọ Ateri, awọn ọmọ Talmoni, awọn ọmọ Akkubu, awọn ọmọ Hatita, awọn ọmọ Ṣobai, gbogbo wọn jẹ, mọkandilogoje.

43 Awọn Netinimu: awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Hasufa, awọn ọmọ Tabbaoti.

44 Awọn ọmọ Kerosi, awọn ọmọ Siha, awọn ọmọ Padoni.

45 Awọn ọmọ Lebana, awọn ọmọ Hagaba, awọn ọmọ Akkubu,

46 Awọn ọmọ Hagabu, awọn ọmọ Ṣalmai, awọn ọmọ Hanani;

47 Awọn ọmọ Giddeli, awọn ọmọ Gahari, awọn ọmọ Reaiah,

48 Awọn ọmọ Resini, awọn ọmọ Nekoda, awọn ọmọ Gassamu,

49 Awọn ọmọ Ussa, awọn ọmọ Pasea, awọn ọmọ Besai,

50 Awọn ọmọ Asna, awọn ọmọ Mehunimi, awọn ọmọ Nefusimi,

51 Awọn ọmọ Bakbuki, awọn ọmọ Hakufa, awọn ọmọ Har-huri,

52 Awọn ọmọ Basluti, awọn ọmọ Mehida, awọn ọmọ Harṣa,

53 Awọn ọmọ Barkosi, awọn ọmọ Sisera, awọn ọmọ Tama,

54 Awọn ọmọ Nesia, awọn ọmọ Hatifa,

55 Awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni: awọn ọmọ Sotai, awọn ọmọ Sofereti, awọn ọmọ Peruda,

56 Awọn ọmọ Jaala, awọn ọmọ Darkoni, awọn ọmọ Giddeli,

57 Awọn ọmọ Ṣefatiah, awọn ọmọ Hattili, awọn ọmọ Pokereti ti Sebaimu, awọn ọmọ Ami.

58 Gbogbo awọn Netinimu, ati awọn ọmọ awọn iranṣẹ Solomoni, jẹ irinwo o din mẹjọ.

59 Awọn wọnyi li o si goke wá lati Telmela, Telkarsa, Kerubu, Addani, ati Immeri: ṣugbọn nwọn kò le fi idile baba wọn hàn, ati iru ọmọ wọn, bi ti inu Israeli ni nwọn iṣe:

60 Awọn ọmọ Delaiah, awọn ọmọ Tobiah, awọn ọmọ Nekoda, ãdọtalelẹgbẹta o le meji.

61 Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn;

62 Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa.

63 Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu.

64 Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo.

65 Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn.

66 Ẹṣin wọn jẹ, ọtadilẹgbẹrin o din mẹrin; ibaka wọn, ojilugba o le marun.

67 Ibakasiẹ wọn, irinwo o le marundilogoji; kẹtẹkẹtẹ wọn, ẹgbẹrinlelọgbọn o din ọgọrin.

68 Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀.

69 Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa.

70 Bẹ̃li awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati omiran ninu awọn enia, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, ati awọn Netinimu ngbe ilu wọn, gbogbo Israeli si ngbe ilu wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10