Esr 6 YCE

Wọ́n Rí Àkọsílẹ̀ Àṣẹ tí Kirusi Ọba Pa

1 NIGBANA ni Dariusi ọba paṣẹ, a si wá inu ile ti a ko iwe jọ si, nibiti a to iṣura jọ si ni Babiloni.

2 A si ri iwe kan ni Ekbatana, ninu ilu olodi ti o wà ni igberiko Medea, ati ninu rẹ̀ ni iwe-iranti kan wà ti a kọ bayi:

3 Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.

4 Ilè okuta nla mẹta, ati ilè igi titun kan: ki a si ṣe inawo rẹ̀ lati inu ile ọba wa:

5 Pẹlupẹlu ki a si kó ohun èlo wura ati ti fàdaka ile Ọlọrun pada, ti Nebukadnessari ti kó lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si ti ko wá si Babiloni, ki a si ko wọn pada, ki a si mu wọn lọ si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, olukuluku ni ipò rẹ̀, ki a si tò wọn si inu ile Ọlọrun.

Dariusi Pàṣẹ pé Kí Wọ́n Máa Bá Iṣẹ́ Lọ

6 Njẹ nisisiyi Tatnai, bãlẹ oke-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ nyin, awọn ara Afarsaki, ti o wà li oke-odò, ki ẹnyin ki o jina si ibẹ.

7 Ẹ jọwọ́ iṣẹ ile Ọlọrun yi lọwọ, ki balẹ awọn ara Juda, ati awọn àgba awọn ara Juda ki nwọn kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.

8 Pẹlupẹlu mo paṣẹ li ohun ti ẹnyin o ṣe fun awọn àgba Juda wọnyi, fun kikọ ile Ọlọrun yi: pe, ninu ẹru ọba, li ara owo-odè li oke-odò, ni ki a mã ṣe ináwo fun awọn enia wọnyi li aijafara, ki a máṣe da wọn duro.

9 Ati eyiti nwọn kò le ṣe alaini ẹgbọrọ akọmalu, ati àgbo, pẹlu ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun si Ọlọrun ọrun, alikama, iyọ, ọti-waini pẹlu ororo, gẹgẹ bi ilana awọn alufa ti o wà ni Jerusalemu, ki a mu fun wọn li ojojumọ laiyẹ̀:

10 Ki nwọn ki o le ru ẹbọ olõrun, didùn si Ọlọrun ọrun, ki nwọn ki o si le ma gbadura fun ẹmi ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀.

11 Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi.

12 Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara.

Wọ́n Ya Tẹmpili sí Mímọ́

13 Nigbana ni Tatnai bãlẹ ni ihahin-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ wọn, gẹgẹ bi eyiti Dariusi ọba ti ranṣẹ, bẹ̃ni nwọn ṣe li aijafara.

14 Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia.

15 A si pari ile yi li ọjọ kẹta oṣu Adari, ti iṣe ọdun kẹfa ijọba Dariusi ọba.

16 Awọn ọmọ Israeli, awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi pẹlu awọn ọmọ ìgbekun ìyoku ṣe ìyasimimọ́ ile Ọlọrun yi pẹlu ayọ̀.

17 Ni iyasimimọ́ ile Ọlọrun yi, ni nwọn si rubọ ọgọrun akọ-malu, igba àgbo, irinwo ọdọ-agutan; ati fun ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli, obukọ mejila gẹgẹ bi iye awọn ẹ̀ya Israeli:

18 Nwọn si fi awọn alufa si gẹgẹ bi ipa wọn ati awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ipa wọn, fun isin Ọlọrun ni Jerusalemu, gẹgẹ bi a ti kọ ọ ninu iwe Mose.

Àjọ Ìrékọjá

19 Awọn ọmọ igbekun si ṣe ajọ irekọja li ọjọ kẹrinla oṣu ekini.

20 Nitoriti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ti wẹ̀ ara wọn mọ́ bi ẹnikan, gbogbo wọn li o si mọ́, nwọn si pa ẹran irekọja fun gbogbo awọn ọmọ igbekun, ati fun awọn arakunrin wọn, awọn alufa, ati fun awọn tikara wọn.

21 Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja.

22 Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10