Esr 5 YCE

Iṣẹ́ Kíkọ́ Tẹmpili Tún Bẹ̀rẹ̀

1 ṢUGBỌN awọn woli, Haggai woli, ati Sekariah ọmọ Iddo, sọ asọtẹlẹ fun awọn Ju ti o wà ni Juda ati Jerusalemu li orukọ Ọlọrun Israeli.

2 Li akoko na ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Jeṣua ọmọ Josadaki dide, nwọn si bẹ̀rẹ si ikọ́ ile Ọlọrun ni Jerusalemu; awọn woli Ọlọrun si wà pẹlu wọn ti nràn wọn lọwọ.

3 Li akoko kanna ni Tatnai, bãlẹ ni ihahin odò, ati Ṣetar-bosnai pẹlu awọn ẹgbẹ wọn, wá si ọdọ wọn, nwọn si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati tun odi yi ṣe?

4 Nigbana ni awa wi fun wọn bayi, pe, Orukọ awọn ọkunrin ti nkọ́ ile yi ti ijẹ?

5 Ṣugbọn oju Ọlọrun wọn mbẹ li ara awọn àgba Juda, ti nwọn kò fi le mu wọn ṣiwọ titi ọ̀ran na fi de ọdọ Dariusi: nigbana ni nwọn si fi èsi pada, nipa iwe nitori eyi.

6 Atunkọ iwe da ti Tatnai, bãlẹ ni ihahin-odò, ati Ṣetar-bosnai, ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ rán si Dariusi ọba: awọn ara Afarsaki ti ihahin-odò.

7 Nwọn fi iwe ranṣẹ si i, ninu eyiti a kọ bayi; Si Dariusi, ọba, alafia gbogbo.

8 Ki ọba ki o mọ̀ pe, awa lọ si igberiko Judea si ile Ọlọrun ẹniti o tobi, ti a fi okuta nlanla kọ, a si tẹ igi si inu ogiri na, iṣẹ yi nlọ siwaju kánkán, o si nṣe rere li ọwọ wọn.

9 Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi?

10 Awa si bère orukọ wọn pẹlu, lati mu ki o da ọ li oju, ki a le kọwe orukọ awọn enia ti iṣe olori ninu wọn.

11 Bayi ni nwọn si fi èsi fun wa wipe, Iranṣẹ Ọlọrun ọrun on aiye li awa iṣe, awa si nkọ́ ile ti a ti kọ́ li ọdun pupọ wọnyi sẹhin, ti ọba nla kan ni Israeli ti kọ́, ti o si ti pari.

12 Ṣugbọn nitoriti awọn baba wa mu Ọlọrun ọrun binu, o fi wọn le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babiloni ti Kaldea, ẹniti o wó ile yi palẹ, ti o si kó awọn enia na lọ si Babiloni.

13 Ṣugbọn li ọdun ekini Kirusi ọba Babiloni, Kirusi ọba na fi aṣẹ lelẹ lati kọ́ ile Ọlọrun yi.

14 Pẹlupẹlu ohun èlo wura ati ti fàdaka ti ile Ọlọrun ti Nebukadnessari ko lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si mu lọ sinu tempili Babiloni, awọn na ni Kirusi ọba ko lati inu tempili Babiloni jade, a si fi wọn le ẹnikan lọwọ, orukọ ẹniti ijẹ Ṣeṣbassari, ẹniti on fi jẹ bãlẹ;

15 On si wi fun u pe, Kó ohun èlo wọnyi lọ, ki o fi wọn si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, ki o si mu ki a tun kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.

16 Nigbana ni Ṣeṣbassari na wá, o si fi ipilẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu lelẹ: ati lati igba na ani titi di isisiyi li o ti mbẹ, ni kikọ kò si ti ipari tan.

17 Njẹ nitorina, bi o ba wu ọba, jẹ ki a wá inu ile iṣura ọba ti o wà nibẹ ni Babiloni, bi o ba ri bẹ̃, pe Kirusi ọba fi aṣẹ lelẹ lati kọ ile Ọlọrun yi ni Jerusalemu, ki ọba ki o sọ eyi ti o fẹ fun wa nipa ọ̀ran yi.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10