10 Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli.
11 Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ.
12 Ṣugbọn pupọ ninu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori awọn baba ti iṣe alàgba, ti nwọn ti ri ile atetekọṣe, nwọn fi ohùn rara sọkun, nigbati a fi ipilẹ ile yi lelẹ li oju wọn, ṣugbọn awọn pupọ si ho iho nla fun ayọ̀:
13 Tobẹ̃ ti awọn enia kò le mọ̀ iyatọ ariwo ayọ̀ kuro ninu ariwo ẹkun awọn enia; nitori awọn enia ho iho nla, a si gbọ́ ariwo na li okere rére.