Esr 3:5-11 YCE

5 Lẹhin na nwọn si ru ẹbọ sisun igbagbogbo ati ti oṣu titun, ati ti gbogbo ajọ Oluwa, ti a si yà si mimọ́, ati ti olukuluku ti o fi tinu-tinu ru ẹbọ atinuwa si Oluwa.

6 Lati ọjọ ikini oṣu keje ni nwọn bẹ̀rẹ lati ma rú ẹbọ sisun si Oluwa. Ṣugbọn a kò ti ifi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ.

7 Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia.

8 Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa.

9 Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi.

10 Nigbati awọn ọmọle si fi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ, nwọn mu awọn alufa duro ninu aṣọ wọn, nwọn mu ipè lọwọ, ati awọn ọmọ Lefi, awọn ọmọ Asafu mu kimbali lọwọ, lati ma yìn Oluwa gẹgẹ bi ìlana Dafidi ọba Israeli.

11 Nwọn si jùmọ kọrin lẹsẹsẹ lati yìn ati lati dupẹ fun Oluwa, nitoripe o ṣeun, ati pe anu rẹ̀ si duro lailai lori Israeli. Gbogbo enia si ho iho nla, nigbati nwọn nyìn Oluwa, nitoriti a fi ipilẹ ile Oluwa lelẹ.