1 NIGBATI awọn ọta Juda ati Benjamini gbọ́ pe awọn ọmọ-igbekun nkọ́ tempili fun Oluwa Ọlọrun Israeli;
2 Nigbana ni nwọn tọ̀ Serubbabeli wá, ati awọn olori awọn baba, nwọn si wi fun wọn pe, ẹ jẹ ki awa ki o ba nyin kọle, nitoriti awa nṣe afẹri Ọlọrun nyin, gẹgẹ bi ẹnyin; awa si nru ẹbọ si ọdọ rẹ̀, lati ọjọ Esarhaddoni, ọba Assuri, ẹniti o mu wa gòke wá ihinyi.
3 Ṣugbọn Serubbabeli, ati Jeṣua ati iyokù ninu awọn olori awọn baba Israeli wi fun wọn pe, Kì iṣe fun awa pẹlu ẹnyin, lati jumọ kọ ile fun Ọlọrun wa; ṣugbọn awa tikarawa ni yio jùmọ kọle fun Oluwa Ọlọrun Israeli gẹgẹ bi Kirusi ọba, ọba Persia, ti paṣẹ fun wa,
4 Nigbana ni awọn enia ilẹ na mu ọwọ awọn enia Juda rọ, nwọn si yọ wọn li ẹnu ninu kikọle na.