Esr 6:5-11 YCE

5 Pẹlupẹlu ki a si kó ohun èlo wura ati ti fàdaka ile Ọlọrun pada, ti Nebukadnessari ti kó lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si ti ko wá si Babiloni, ki a si ko wọn pada, ki a si mu wọn lọ si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, olukuluku ni ipò rẹ̀, ki a si tò wọn si inu ile Ọlọrun.

6 Njẹ nisisiyi Tatnai, bãlẹ oke-odò, Ṣetarbosnai, ati awọn ẹgbẹ nyin, awọn ara Afarsaki, ti o wà li oke-odò, ki ẹnyin ki o jina si ibẹ.

7 Ẹ jọwọ́ iṣẹ ile Ọlọrun yi lọwọ, ki balẹ awọn ara Juda, ati awọn àgba awọn ara Juda ki nwọn kọ ile Ọlọrun yi si ipò rẹ̀.

8 Pẹlupẹlu mo paṣẹ li ohun ti ẹnyin o ṣe fun awọn àgba Juda wọnyi, fun kikọ ile Ọlọrun yi: pe, ninu ẹru ọba, li ara owo-odè li oke-odò, ni ki a mã ṣe ináwo fun awọn enia wọnyi li aijafara, ki a máṣe da wọn duro.

9 Ati eyiti nwọn kò le ṣe alaini ẹgbọrọ akọmalu, ati àgbo, pẹlu ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun si Ọlọrun ọrun, alikama, iyọ, ọti-waini pẹlu ororo, gẹgẹ bi ilana awọn alufa ti o wà ni Jerusalemu, ki a mu fun wọn li ojojumọ laiyẹ̀:

10 Ki nwọn ki o le ru ẹbọ olõrun, didùn si Ọlọrun ọrun, ki nwọn ki o si le ma gbadura fun ẹmi ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀.

11 Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi.