7 Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin.
8 Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin.
9 Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji.
10 Ati ninu awọn ọmọ Ṣelomiti; ọmọ Josafiah, ati pẹlu rẹ̀, ọgọjọ ọkunrin.
11 Ati ninu awọn ọmọ Bebai; Sekariah, ọmọ Bebai, ati pẹlu rẹ̀, ọkunrin mejidilọgbọn.
12 Ati ninu awọn ọmọ Asgadi; Johanani ọmọ Hakkatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọfa ọkunrin.
13 Ati ninu awọn ọmọ ikẹhin Adonikamu, orukọ awọn ẹniti iṣe wọnyi, Elifeleti, Jeieli, ati Ṣemaiah, ati pẹlu wọn, ọgọta ọkunrin.