1 LẸHIN nkan wọnyi, nigbati ibinu Ahaswerusi ọba wa tuka, o ranti Faṣti, ati ohun ti o ti ṣe, ati aṣẹ ti a ti pa nitori rẹ̀.
2 Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba, ti nṣe iranṣẹ fun u, wi pe, jẹ ki a wá awọn wundia ti o li ẹwà fun ọba.
3 Ki ọba ki o si yàn olori ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣà awọn wundia ti o li ẹwà jọ wá si Ṣuṣani ãfin, si ile awọn obinrin, si ọdọ Hegai, ìwẹfa ọba olutọju awọn obinrin; ki a si fi elo ìwẹnumọ́ wọn fun wọn:
4 Ki wundia na ti o ba wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba, o si ṣe bẹ̃.
5 Ọkunrin ara Juda kan wà ni Ṣuṣani ãfin, orukọ ẹniti ijẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣemei, ọmọ Kisi, ara Benjamini.
6 Ẹniti a ti mu lọ lati Jerusalemu pẹlu ìgbekun ti a kó lọ pẹlu Jekoniah, ọba Juda, ti Nebukadnessari, ọba Babeli ti kó lọ.
7 On li o si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitori kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, wundia na si li ẹwà, o si dara lati wò; ẹniti, nigbati baba ati iya rẹ̀ ti kú tan, Mordekai mu u ṣe ọmọbinrin ontikalarẹ̀,
8 O si ṣe, nigbati a gbọ́ ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀, nigbati a si ṣà ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si ọwọ Hegai, a si mu Esteri wá si ile ọba pẹlu si ọwọ Hegai, olutọju awọn obinrin.
9 Wundia na si wù u, o si ri ojurere gbà lọdọ rẹ̀; o si yara fi elo ìwẹnumọ́ rẹ̀ fun u, ati ipin onjẹ ti o jẹ tirẹ̀, ati obinrin meje ti a yàn fun u lati ile ọba wá: on si ṣi i lọ ati awọn wundia rẹ̀ si ibi ti o dara jù ni ile awọn obinrin.
10 Esteri kò ti ifi awọn enia rẹ̀, tabi awọn ibatan rẹ̀ hàn; nitori Mordekai paṣẹ fun u ki o máṣe fi hàn.
11 Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ alafia Esteri, ati bi yio ti ri fun u.
12 Njẹ nigbati o kan olukuluku wundia lati wọ̀ ile tọ̀ Ahaswerusi ọba lọ, lẹhin igbati on ba ti gbe oṣù mejila, gẹgẹ bi iṣe awọn obinrin, (nitori bayi ni ọjọ ìwẹnumọ́ wọn pari, oṣù mẹfa ni nwọn fi ikùn òroro ojiá, ati oṣù mẹfa òroro olõrùn didùn, ati pẹlu ohun elo ìwẹnumọ́ awọn obinrin):
13 Bayi ni wundia na iwá si ọdọ ọba; ohunkohun ti o ba bère li a si ifi fun u lati ba a lọ, lati ile awọn obinrin lọ si ile ọba.
14 Li aṣãlẹ on a lọ, ni õrọ ijọ keji on a si pada si ile keji ti awọn obinrin, si ọwọ Ṣaaṣgasi, ìwẹfa, ọba, ti nṣe olutọju awọn obinrin, on kò si gbọdọ wọle tọ̀ ọba wá mọ, bikoṣepe inu ọba ba dùn si i, ti a ba si pè e li orukọ.
15 Njẹ nigbati o kan Esteri, ọmọ Abihaili, arakunrin Mordekai, ẹniti o mu u ṣe ọmọ ara rẹ̀, lati wọle tọ̀ ọba lọ, on kò bère ohunkohun, bikoṣe ohun ti Hegai, ìwẹfa ọba, olutọju awọn obinrin paṣẹ. Esteri si ri ojurere lọdọ gbogbo ẹniti nwò o.
16 Bẹ̃li a mu Esteri wá si ọdọ Ahaswerusi ọba, sinu ile ọba, li oṣù kẹwa, ti iṣe oṣù Tibeti, li ọdun keje ijọba rẹ̀.
17 Ọba si fẹràn Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri ore-ọfẹ ati ojurere lọdọ rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; tobẹ̃ ti o fi gbe ade ọba kà a li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti.
18 Ọba si sè àse nla kan fun gbogbo awọn olori rẹ̀, ati awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ani àse ti Esteri; o si fi isimi fun awọn ìgberiko rẹ̀, o si ṣe itọrẹ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.
19 Nigbati a si kó awọn wundia na jọ li ẹrinkeji, nigbana ni Mordekai joko li ẹnu ọ̀na ile ọba.
20 Esteri kò ti ifi awọn ibatan, tabi awọn enia rẹ̀ hàn titi disisiyi bi Mordekai ti paṣẹ fun u: nitori Esteri npa ofin Mordekai mọ́, bi igba ti o wà li abẹ itọ́ rẹ̀.
21 Li ọjọ wọnni, nigbati Mordekai njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba, meji ninu awọn iwẹfa ọba, Bigtani ati Tereṣi, ninu awọn ti nṣọ iloro, nwọn binu, nwọn si nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba.
22 Nkan na si di mimọ̀ fun Mordekai, o si sọ fun Esteri ayaba; Esteri si fi ọ̀ran na hàn ọba li orukọ Mordekai.
23 Nigbati nwọn si wadi ọ̀ran na, nwọn ri idi rẹ̀; nitorina a so awọn mejeji rọ̀ sori igi; a si kọ ọ sinu iwé-iranti niwaju ọba.