Est 4 YCE

Mordekai Wá Ìrànlọ́wọ́ Ẹsteri

1 Nigbati Mordekai mọ̀ gbogbo ohun ti a ṣe, Mordekai fa aṣọ rẹ̀ ya, o si fi aṣọ-ọ̀fọ on ẽru bò ara, o si jade lọ si ãrin ilu na, o si sọkun kikan ati kikoro.

2 O tilẹ wá siwaju ẹnu-ọna ile ọba: nitori kò si ẹnikan ti o fi aṣọ-ọfọ si ara ti o gbọdọ wọ̀ ẹnu-ọ̀na ile ọba.

3 Ati ni gbogbo ìgberiko, nibiti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, ọ̀fọ nla ba gbogbo awọn Ju; ati ãwẹ, ati ẹkún, ati ipohùnrere; ọ̀pọlọpọ li o si dubulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ninu ẽru.

4 Bẹ̃li awọn iranṣẹbinrin Esteri ati awọn ìwẹfa rẹ̀ wá, nwọn si sọ fun u. Nigbana ni inu ayaba bajẹ gidigidi; o si fi aṣọ ranṣẹ lati fi wọ̀ Mordekai, ati lati mu aṣọ-ọ̀fọ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ṣugbọn on kò gbà a.

5 Nigbana ni Esteri pè Hataki, ọkan ninu awọn ìwẹfa ọba, ẹniti o ti yàn lati duro niwaju rẹ̀, o si rán a si Mordekai lati mọ̀ ohun ti o ṣe, ati nitori kini?

6 Bẹ̃ni Hataki jade tọ̀ Mordekai lọ si ita ilu niwaju ẹnu-ọ̀na ile ọba.

7 Mordekai si sọ ohun gbogbo ti o ri to fun u, ati ti iye owo fadaka ti Hamani ti ṣe ileri lati san si ile iṣura ọba, nitori awọn Ju, lati pa wọn run.

8 Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀.

9 Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri.

10 Esteri si tun sọ fun Hataki, o si rán a si Mordekai.

11 Pe, gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ati awọn enia ìgberiko ọba li o mọ̀ pe, ẹnikẹni ibaṣe ọkunrin tabi obinrin, ti o ba tọ̀ ọba wá sinu àgbala ti inu, ti a kò ba pè, ofin rẹ̀ kan ni, ki a pa a, bikoṣe iru ẹniti ọba ba nà ọpá alade wura si, ki on ki o le yè: ṣugbọn a kò ti ipè mi lati wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ lati ìwọn ọgbọn ọjọ yi wá.

12 Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai.

13 Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ.

14 Nitori bi iwọ ba pa ẹnu rẹ mọ́ patapata li akokò yi, nigbana ni iranlọwọ ati igbala awọn Ju yio dide lati ibomiran wá; ṣugbọn iwọ ati ile baba rẹ li a o parun: tali o si mọ̀ bi nitori iru akokò bayi ni iwọ ṣe de ijọba?

15 Nigbana ni Esteri rán wọn lọ ifi èsi yi fun Mordekai pe,

16 Lọ, pè awọn Ju ti a le ri ni Ṣuṣani jọ, ki ẹnyin si ma gbãwẹ, fun mi, ki ẹnyin ki o máṣe jẹun, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ni ijọ mẹta t'ọsan t'oru: emi pẹlu ati awọn iranṣẹbinrin mi yio gbãwẹ bẹ̃ gẹgẹ; bẹ̃li emi o si wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ, ti o lòdi si ofin; bi mo ba ṣègbe, mo ṣègbe.

17 Bẹ̃ni Mordekai ba ọ̀na rẹ̀ lọ, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Esteri ti paṣẹ fun u.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10