Est 5 YCE

Ẹsteri Pe Ọba ati Hamani sí Àsè

1 O si ṣe li ọjọ kẹta, ni Esteri wọ̀ aṣọ ayaba rẹ̀, o si duro ni àgbala ile ọba ti o wà ninu, lọgangan ile ọba: ọba si joko lori ìtẹ ijọba rẹ̀ ni ile ọba, ti o kọjusi ẹnu-ọ̀na ile na.

2 O si ṣe nigbati ọba ri ti Esteri ayaba duro ni àgbala, on si ri ore-ọfẹ loju rẹ̀: ọba si nà ọ̀pá alade wura ti o wà lọwọ rẹ̀ si Esteri. Esteri si sunmọ ọ, o si fi ọwọ kàn ori ọpá alade na.

3 Nigbana ni ọba bi i pe, kini iwọ nfẹ́, Esteri ayaba? ati kini ẹ̀bẹ rẹ̀? ani de idajì ijọba li a o si fi fun ọ.

4 Esteri si dahùn pe, bi o ba dara loju ọba, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá loni si àse mi, ti mo ti mura silẹ fun u.

5 Nigbana ni ọba wi pe, ẹ mu ki Hamani ki o yara, ki on ki o le ṣe bi Esteri ti wi. Bẹ̃ni ọba ati Hamani wá si àse na ti Esteri ti sè silẹ.

6 Ọba si wi fun Esteri nibiti nwọn gbe nmu ọti-waini pe, kini ibere rẹ? a o si fi fun ọ: ki si ni ẹ̀bẹ rẹ? ani de idajì ijọba, a o si ṣe e.

7 Nigbana ni Esteri dahùn, o si wi pe, ẹ̀bẹ mi ati ibère mi ni pe,

8 Bi mo ba ri ore-ọfẹ loju ọba, bi o ba si wù ọba lati fi ohun ti emi ntọrọ fun mi, ati lati ṣe ohun ti emi mbère fun mi, jẹ ki ọba ati Hamani ki o wá si àse ti emi o si tun sè fun wọn, emi o si ṣe li ọla bi ọba ti wi.

Hamani Ṣe Ètò láti Pa Modekai

9 Nigbana ni Hamani jade lọ li ọjọ na tayọ̀tayọ̀, ati pẹlu inu didùn: ṣugbọn nigbati Hamani ri Mordekai li ẹnu ọ̀na ile ọba pe, kò dide duro, bẹ̃ni kò pa ara rẹ̀ da fun on, Hamani kún fun ibinu si Mordekai.

10 Ṣugbọn Hamani kó ara rẹ̀ ni ijanu: nigbati o si de ile, o ranṣẹ lọ ipè awọn ọrẹ rẹ̀, ati Sereṣi aya rẹ̀.

11 Hamani si ròhin ogo ọrọ̀ rẹ̀, ati ọ̀pọlọpọ awọn ọmọ rẹ̀, ati ninu ohun gbogbo ti ọba fi gbe e ga, ati bi o ti gbe on ga jù awọn ijoye, ati awọn ọmọ-ọdọ ọba lọ.

12 Hamani si wi pẹlu pe, ani Esteri ayaba kò mu ki ẹnikẹni ki o ba ọba wá si ibi àse ti o ti sè bikoṣe emi nikan; li ọla ẹ̀wẹ li a si tun pè mi pẹlu ọba lati wá si ọdọ rẹ̀,

13 Ṣugbọn gbogbo wọnyi kò di nkankan fun mi, niwọ̀n igbati mo ba ri Mordekai, ara Juda nì, ti o joko li ẹnu ọ̀na ile ọba.

14 Nigbana ni Sereṣi aya rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ wi fun u pe, Jẹ ki a rì igi kan, ki o ga ni ãdọta igbọnwọ, ati li ọla ni ki o ba ọba sọ ọ ki a so Mordekai rọ̀ nibẹ: iwọ̀ o si fi ayọ̀ ba ọba lọ si ibi àse. Nkan yi dùn mọ Hamani, o si rì igi na.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10