Est 3 YCE

Hamani Dìtẹ̀ láti Pa Àwọn Juu Run

1 LẸHIN nkan wọnyi ni Ahaswerusi ọba gbe Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi ga, o si gbe e lekè, o si fi ijoko rẹ̀ lekè gbogbo awọn ijoye ti o wà pẹlu rẹ̀.

2 Gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, kunlẹ nwọn si wolẹ fun Hamani: nitori ọba ti paṣẹ bẹ̃ nitori rẹ̀. Ṣugbọn Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò si wolẹ fun u.

3 Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba, ti nwọn wà li ẹnu ọ̀na ọba, wi fun Mordekai pe, ẽṣe ti iwọ fi nré ofin ọba kọja?

4 O si ṣe, nigbati nwọn wi fun u lojojumọ, ti on kò si gbọ́ ti wọn, nwọn sọ fun Hamani, lati wò bi ọ̀ran Mordekai yio ti le ri: nitori on ti wi fun wọn pe, enia Juda ni on.

5 Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu.

6 O si jẹ abùku loju rẹ̀ lati gbe ọwọ le Mordekai nikan; nitori nwọn ti fi awọn enia Mordekai hàn a: nitorina gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo ijọba Ahaswerusi, ni Hamani wá ọ̀na lati parun, ani awọn enia Mordekai.

7 Li oṣù kini, eyinì ni oṣù Nisani, li ọdun kejila ijọba Ahaswerusi, nwọn da purimu, eyinì ni, ìbo, niwaju Hamani, lati ọjọ de ọjọ, ati lati oṣù de oṣù lọ ide oṣù kejila, eyinì ni oṣù Adari.

8 Hamani si sọ fun Ahaswerusi ọba pe, awọn enia kan fọn kakiri, nwọn si tuka lãrin awọn enia ni gbogbo ìgberiko ijọba rẹ, ofin wọn si yatọ si ti gbogbo enia; bẹ̃ni nwọn kò si pa ofin ọba mọ́; nitorina kò yẹ fun ọba lati da wọn si.

9 Bi o ba wù ọba, jẹ ki a kọwe rẹ̀ pe, ki a run wọn: emi o si wọ̀n ẹgbãrun talenti fadaka fun awọn ti a fi iṣẹ na rán, ki nwọn ki o le mu u wá sinu ile iṣura ọba.

10 Ọba si bọ́ oruka rẹ̀ kuro li ọwọ rẹ̀, o si fi fun Hamani, ọmọ Medata, ara Agagi, ọta awọn Ju.

11 Ọba si wi fun Hamani pe, a fi fadaka na bùn ọ, ati awọn enia na pẹlu, lati fi wọn ṣe bi o ti dara loju rẹ.

12 Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀.

13 A si fi iwe na rán awọn òjiṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, lati parun, lati pa, ati lati mu ki gbogbo enia Juda, ati ọ̀dọ ati arugbo, awọn ọmọde, ati awọn obinrin ki o ṣegbe ni ọjọ kan, ani li ọjọ kẹtala, oṣù kejila, ti iṣe oṣù Adari, ati lati kó ohun iní wọn fun ijẹ.

14 Ọ̀ran iwe na ni lati paṣẹ ni gbogbo igberiko, lati kede rẹ̀ fun gbogbo enia, ki nwọn ki o le mura de ọjọ na.

15 Awọn ojiṣẹ na jade lọ, nwọn si yara, nitori aṣẹ ọba ni, a si pa aṣẹ na ni Ṣuṣani ãfin. Ati ọba ati Hamani joko lati mu ọti; ṣugbọn ilu Ṣuṣani dãmu.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10