3 Ati ni gbogbo ìgberiko, nibiti ofin ọba, ati aṣẹ rẹ̀ ba de, ọ̀fọ nla ba gbogbo awọn Ju; ati ãwẹ, ati ẹkún, ati ipohùnrere; ọ̀pọlọpọ li o si dubulẹ ninu aṣọ-ọ̀fọ, ati ninu ẽru.
4 Bẹ̃li awọn iranṣẹbinrin Esteri ati awọn ìwẹfa rẹ̀ wá, nwọn si sọ fun u. Nigbana ni inu ayaba bajẹ gidigidi; o si fi aṣọ ranṣẹ lati fi wọ̀ Mordekai, ati lati mu aṣọ-ọ̀fọ rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ṣugbọn on kò gbà a.
5 Nigbana ni Esteri pè Hataki, ọkan ninu awọn ìwẹfa ọba, ẹniti o ti yàn lati duro niwaju rẹ̀, o si rán a si Mordekai lati mọ̀ ohun ti o ṣe, ati nitori kini?
6 Bẹ̃ni Hataki jade tọ̀ Mordekai lọ si ita ilu niwaju ẹnu-ọ̀na ile ọba.
7 Mordekai si sọ ohun gbogbo ti o ri to fun u, ati ti iye owo fadaka ti Hamani ti ṣe ileri lati san si ile iṣura ọba, nitori awọn Ju, lati pa wọn run.
8 Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀.
9 Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri.