7 Mordekai si sọ ohun gbogbo ti o ri to fun u, ati ti iye owo fadaka ti Hamani ti ṣe ileri lati san si ile iṣura ọba, nitori awọn Ju, lati pa wọn run.
8 Ati pẹlu, o fi iwe aṣẹ na pãpã, ti a pa ni Ṣuṣani lati pa awọn Ju run, le e lọwọ, lati fi hàn Esteri, ati lati sọ fun u, ati lati paṣẹ fun u ki on ki o wọle tọ̀ ọba lọ, lati bẹ̀bẹ lọwọ rẹ̀, ati lati bẹ̀bẹ niwaju rẹ̀, nitori awọn enia rẹ̀.
9 Hataki si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ Mordekai fun Esteri.
10 Esteri si tun sọ fun Hataki, o si rán a si Mordekai.
11 Pe, gbogbo awọn iranṣẹ ọba, ati awọn enia ìgberiko ọba li o mọ̀ pe, ẹnikẹni ibaṣe ọkunrin tabi obinrin, ti o ba tọ̀ ọba wá sinu àgbala ti inu, ti a kò ba pè, ofin rẹ̀ kan ni, ki a pa a, bikoṣe iru ẹniti ọba ba nà ọpá alade wura si, ki on ki o le yè: ṣugbọn a kò ti ipè mi lati wọ̀ ile tọ̀ ọba lọ lati ìwọn ọgbọn ọjọ yi wá.
12 Nwọn si sọ ọ̀rọ Esteri fun Mordekai.
13 Nigbana ni Mordekai sọ ki a da Esteri lohùn pe, Máṣe rò ninu ara rẹ pe, iwọ o là ninu ile ọba jù gbogbo awọn Ju lọ.