1 Li oru na ọba kò le sùn, o si paṣẹ pe, ki a mu iwe iranti, ani irohin awọn ọjọ wá, a si kà wọn niwaju ọba.
2 A si ri pe, ati kọ ọ pe, Mordekai ti sọ ti Bigtani, ati Tereṣi, awọn ìwẹfa ọba meji, oluṣọ iloro, awọn ẹniti nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba.
3 Ọba si wi pe, Iyìn ati ọlá wo li a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wi pe, a kò ṣe nkankan fun u.
4 Ọba si wi pe, Tani mbẹ ni àgbala? Hamani si ti de àgbala akọkàn ile ọba, lati ba ọba sọ ọ lati so Mordekai rọ̀ sori igi giga ti o ti rì fun u.