6 Bẹ̃ni Hamani si wọle wá, Ọba si wi fun u pe, kini a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun? Njẹ Hamani rò ninu ọkàn ara rẹ̀ pe, Tani inu ọba le dùn si lati bù ọlá fun jù emi tikalami lọ?
7 Hamani si da ọba lohùn pe, ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
8 Jẹ ki a mu aṣọ ọba ti ọba ima wọ̀, ati ẹṣin ti ọba ima gùn, ati ade ọba ti ima gbe kà ori rẹ̀ wá;
9 Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
10 Nigbana ni ọba wi fun Hamani pe, yara kánkán, mu ẹ̀wu ati ẹṣin na, bi iwọ ti wi, ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun Mordekai, ara Juda nì, ti njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba: ohunkohun kò gbọdọ yẹ̀ ninu ohun ti iwọ ti sọ.
11 Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
12 Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀.