9 Ki a si fi ẹ̀wu ati ẹṣin yi le ọwọ ọkan ninu awọn ijoye ọba ti o lọlajùlọ, ki nwọn fi ṣe ọṣọ fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun, ki o si mu u gẹṣin là igboro ilu, ki o si ma kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na, ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
10 Nigbana ni ọba wi fun Hamani pe, yara kánkán, mu ẹ̀wu ati ẹṣin na, bi iwọ ti wi, ki o si ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun Mordekai, ara Juda nì, ti njoko li ẹnu ọ̀na ile ọba: ohunkohun kò gbọdọ yẹ̀ ninu ohun ti iwọ ti sọ.
11 Nigbana ni Hamani mu aṣọ ati ẹṣin na, o si ṣe Mordekai li ọṣọ́, o si mu u là igboro ilu lori ẹṣin, o si kigbe niwaju rẹ̀ pe, Bayi li a o ṣe fun ọkunrin na ẹniti inu ọba dùn si lati bù ọlá fun.
12 Mordekai si tun pada wá si ẹnu-ọ̀na ile ọba, ṣugbọn Hamani yara lọ si ile rẹ̀ ti on ti ibinujẹ, o si bò ori rẹ̀.
13 Hamani si sọ gbogbo ohun ti o ba a, fun Sereṣi obinrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn enia rẹ̀, amoye, ati Sereṣi obinrin rẹ̀, wi fun u pe, Bi Mordekai ba jẹ iru-ọmọ awọn Ju, niwaju ẹniti iwọ ti bẹ̀rẹ si iṣubu na, iwọ, kì yio le bori rẹ̀, ṣugbọn iwọ o ṣubu niwaju rẹ̀ dandan.
14 Bi nwọn si ti mba a sọ̀rọ lọwọ, awọn ìwẹfa ọba de, lati wá mu Hamani yára wá si ibi àse ti Esteri sè.