13 Dafidi si bi ọmọdekunrin na ti o rò fun u wipe, Nibo ni iwọ ti wá? On si da a li ohùn pe, Ọmọ alejo kan, ara Amaleki li emi iṣe.
14 Dafidi si wi fun u pe, E ti ri ti iwọ kò fi bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati fi pa ẹni-àmi-ororo Oluwa?
15 Dafidi si pe ọkan ninu awọn ọmọdekunrin, o si wipe, Sunmọ ọ, ki o si kọ lu u. O si kọ lu u, on si kú.
16 Dafidi si wi fun u pe Ẹjẹ rẹ mbẹ li ori ara rẹ; nitoripe ẹnu rẹ li o fi jẹwọ pe, Emi li o pa ẹni-àmi-ororo Oluwa.
17 Dafidi si fi orin ọ̀fọ yi ṣọ̀fọ̀ lori Saulu ati lori Jonatani ọmọ rẹ̀:
18 O si pa aṣẹ lati kọ́ awọn ọmọ Juda ni ilò ọrun: wõ, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri.
19 Ẹwà rẹ Israeli li a pa li oke giga rẹ: wò bi awọn alagbara ti ṣubu!