2. Sam 2 YCE

Wọ́n fi Dafidi Jọba Juda

1 O si ṣe lẹhin eyi, Dafidi si bere lọwọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke lọ si ọkan ni ilu Juda wọnni bi? Oluwa si wi fun u pe, Goke lọ: Dafidi si wipe, niha ibo ni ki emi ki o lọ? On si wipe, Ni Hebroni.

2 Dafidi si goke lọ si ibẹ ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli ati Abigaili obinrin Nabali ara Karmeli.

3 Dafidi si mu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ goke, olukuluku ton ti ara ile rẹ̀: nwọn si joko ni ilu Hebroni wọnni.

4 Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin Jabeṣi Gileadi li o sinkú Saulu.

5 Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi o si wi fun wọn pe, Alabukun fun li ẹnyin lati ọwọ́ Oluwa wá, bi ẹnyin ti ṣe õre yi si oluwa nyin, si Saulu, ani ti ẹ fi sinkú rẹ̀.

6 Njẹ ki Oluwa ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi na yio si san ore yi fun nyin, nitori ti ẹnyin ṣe nkan yi.

7 Njẹ ẹ si mu ọwọ́ nyin le, ki ẹ si jẹ ẹni-alagbara: nitoripe Saulu oluwa nyin ti kú, ile Juda si ti fi àmi-ororo yàn mi li ọba wọn.

Wọ́n fi Iṣiboṣẹti jọba Israẹli

8 Ṣugbọn Abneri ọmọ Neri olori ogun Saulu si mu Iṣboṣeti ọmọ Saulu, o si mu u kọja si Mahanaimu;

9 On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.

10 Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹrẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn idile Juda ntọ̀ Dafidi lẹhin.

11 Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa.

12 Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni.

13 Joabu ọmọ Seruia, ati awọn iranṣẹ Dafidi si jade, nwọn si jọ pade nibi adagun Gibeoni: nwọn si joko, ẹgbẹ kan li apa ihin adagun, ẹgbẹ keji li apa keji adagun.

14 Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ta pọrọ́ niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki wọn ki o dide.

15 Nigbana li awọn mejila ninu ẹya Benjamini ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu dide, nwọn si kọja siha keji; mejila ninu awọn ọmọ Dafidi si dide.

16 Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori mu, olukuluku si tẹ idà rẹ̀ bọ ẹnikeji rẹ̀ ni ihà: nwọn si jọ ṣubu lulẹ: nitorina li a si ṣe npe orukọ ibẹ na ni Helkatihassurimu, ti o wà ni Gibeoni.

17 Ijà na si kan gidigidi ni ijọ na, a si le Abneri ati awọn ọkunrin Israeli niwaju awọn ọmọ Dafidi.

18 Awọn ọmọ Seruia mẹtẹta si mbẹ nibẹ, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fẹrẹ bi ẹsẹ agbọnrin ti o wà ni pápa.

19 Asaheli si nlepa Abneri; bi on ti nlọ kò si yipada si ọwọ ọtun, tabi si ọwọ́ osì lati ma tọ Abneri lẹhin.

20 Nigbana ni Abneri boju wo ẹhin rẹ̀, o si bere pe, Iwọ Asaheli ni? On si dahùn pe, Emi ni.

21 Abneri si wi fun u pe, Iwọ yipada si apakan si ọwọ́ ọtun rẹ, tabi si osì rẹ, ki iwọ ki o si di ọkan mu ninu awọn ọmọkunrin, ki o si mu ihamọra rẹ̀. Ṣugbọn Asaheli kọ̀ lati pada lẹhin rẹ̀.

22 Abneri si tun wi fun Asaheli pe, Pada lẹhin mi, ẽṣe ti emi o fi lu ọ bolẹ? bawo li emi o ti ṣe gbe oju soke si Joabu arakunrin rẹ?

23 Ṣugbọn o si kọ̀ lati pada: Abneri si fi òdi ọ̀kọ gun u labẹ inu, ọ̀kọ na si jade li ẹhin rẹ̀: on si ṣubu lulẹ nibẹ, o si kú ni ibi kanna; o si ṣe, gbogbo enia ti o de ibiti Asaheli gbe ṣubu si, ti o si kú, si duro jẹ.

24 Joabu ati Abiṣai si lepa Abneri: õrun si wọ̀, nwọn si de oke ti Amma ti o wà niwaju Gia li ọ̀na iju Gibeoni.

25 Awọn ọmọ Benjamini si ko ara wọn jọ nwọn tẹle Abneri, nwọn si wa di ẹgbẹ kan, nwọn si duro lori oke kan.

26 Abneri si pe Joabu, o si bi i lere pe, Idà yio ma parun titi lailai bi? njẹ iwọ kò iti mọ̀ pe yio koro nikẹhin? njẹ yio ha ti pẹ to ki iwọ ki o to sọ fun awọn enia na, ki nwọn ki o dẹkun lati ma lepa ará wọn?

27 Joabu si wipe, Bi Ọlọrun ti mbẹ, bikoṣe bi iwọ ti wi, nitotọ, li owurọ̀ li awọn enia na iba ti goke lọ, olukuluku iba ti pada lẹhin arakunrin rẹ̀.

28 Joabu si fún ipè, gbogbo enia si duro jẹ, nwọn kò si lepa Israeli mọ, bẹ̃ni nwọn kò si tun jà mọ.

29 Abneri ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si fi gbogbo oru na rìn ni pẹtẹlẹ, nwọn si kọja Jordani, nwọn si rìn ni gbogbo Bitroni, nwọn si wá si Mahanaimu.

30 Joabu si dẹkun ati ma tọ Abneri lẹhin: o si ko gbogbo awọn enia na jọ, enia mọkandi-logun li o kú pẹlu Asaheli ninu awọn iranṣẹ Dafidi.

31 Ṣugbọn awọn iranṣẹ Dafidi si lù bolẹ ninu awọn enia Benjamini; ati ninu awọn ọmọkunrin Abneri; ojì-di-ni-irin-wo enia li o kú.

32 Nwọn si gbe Asaheli, nwọn si sin i sinu ibojì baba rẹ̀ ti o wà ni Betlehemu. Joabu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ fi gbogbo oru na rin, ilẹ si mọ́ wọn si Hebroni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8