2. Sam 5 YCE

Dafidi di Ọba Israẹli ati ti Juda

1 GBOGBO ẹya Israeli si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wipe, Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.

2 Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.

3 Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli.

4 Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.

5 O jọba ni Hebroni li ọdun meje on oṣu mẹfa lori Juda: o si jọba ni Jerusalemu li ọdun mẹtalelọgbọn lori gbogbo Israeli ati Juda.

6 Ati ọba ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ Jerusalemu sọdọ awọn ara Jebusi, awọn enia ilẹ na: awọn ti o si ti wi fun Dafidi pe, Bikoṣepe iwọ ba mu awọn afọju ati awọn arọ kuro, iwọ ki yio wọ ìhin wá: nwọn si wipe, Dafidi ki yio lè wá sihin.

7 Ṣugbọn Dafidi si fi agbara gbà ilu odi Sioni: eyi na ni iṣe ilu Dafidi.

8 Dafidi si sọ lọjọ na pe, Ẹnikẹni ti yio kọlu awọn ara Jebusi, jẹ ki o gbà oju àgbàrá, ki o si kọlu awọn arọ ati awọn afọju ti ọkàn Dafidi korira. Nitorina ni nwọn ṣe wipe, Afọju ati arọ wà nibẹ, kì yio le wọle.

9 Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.

10 Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀.

11 Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.

12 Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.

13 Dafidi si tun mu awọn alè ati aya si i lati Jerusalemu wá, lẹhin igbati o ti Hebroni bọ̀: nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin fun Dafidi.

14 Eyi si ni orukọ awọn ti a bi fun u ni Jerusalemu, Ṣammua ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni,

15 Ati Ibehari, ati Eliṣua, ati Nefegi, ati Jafia,

16 Ati Eliṣama, ati Eliada, ati Elifaleti,

Dafidi Ṣẹgun Àwọn Ará Filistia

17 Ṣugbọn nigbati awọn Filistini gbọ́ pe, nwọn ti fi Dafidi jọba lori Israeli, gbogbo awọn Filistini si goke wá lati wa Dafidi; Dafidi si gbọ́, o si sọkalẹ lọ si ilu odi.

18 Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu.

19 Dafidi si bere lọdọ Oluwa, pe, Ki emi ki o goke tọ̀ awọn Filistini bi? iwọ o fi wọn le mi lọwọ bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe, Goke lọ: nitoripe, dajudaju emi o fi awọn Filistini le ọ lọwọ.

20 Dafidi si de Baal-perasimu, Dafidi si pa wọn nibẹ, o si wipe, Oluwa ti ya lù awọn ọtá mi niwaju mi, gẹgẹ bi omi iti ya. Nitorina li on ṣe pe orukọ ibẹ na ni Baal-perasimu.

21 Nwọn si fi oriṣa wọn silẹ nibẹ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si ko wọn.

22 Awọn Filistini si tún goke wá, nwọn si tàn ara wọn kalẹ ni afonifoji Refaimu.

23 Dafidi si bere lọdọ Oluwa, on si wipe, Máṣe goke lọ; ṣugbọn bù wọn lẹhin, ki o si kọlu wọn niwaju awọn igi Baka.

24 Yìo si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lori awọn igi Baka na, nigbana ni iwọ o si yara, nitoripe nigbana li Oluwa yio jade lọ niwaju rẹ, lati kọlu ogun awọn Filistini.

25 Dafidi si ṣe bẹ̃, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun u; o si kọlu awọn Filistini lati Geba titi o fi de Gaseri.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8