2. Sam 8 YCE

Àwọn Ogun tí Dafidi jà ní àjàṣẹ́gun

1 O SI ṣe, lẹhin eyi, Dafidi si kọlu awọn Filistini, o si tẹri wọn ba: Dafidi si gbà Metegamma lọwọ awọn Filistini.

2 O si kọlu Moabu, a si fi okùn tita kan diwọ̀n wọn, o si da wọn bu'lẹ; o si ṣe oṣuwọn okun meji ni iye awọn ti on o pa, ati ẹkún oṣuwọn okùn kan ni iye awọn ti yio dá si. Awọn ara Moabu si nsìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá.

3 Dafidi si kọlu Hadadeseri ọmọ Rehobu, ọba Soba, bi on si ti nlọ lati gbà ilẹ rẹ̀ pada ti o gbè odo Eufrate.

4 Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn.

5 Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria.

6 Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.

7 Dafidi si gbà aṣà wura ti o wà lara awọn iranṣẹ Hadadeseri, o si ko wọn wá si Jerusalemu.

8 Lati Beta, ati lati Berotai, awọn ilú Hadadeseri, ni Dafidi ọba si ko ọ̀pọlọpọ idẹ wá.

9 Nigbati Toi ọba Hamati si gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri,

10 Toi si ran Joramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba, lati ki i, ati lati sure fun u, nitoripe o ti ba Hadadeseri jagun, o si ti pa a: nitoriti Hadadeseri sa ti ba Toi jagun. Joramu si ni ohun elo fadaka, ati ohun elo wura, ati ohun elo idẹ li ọwọ́ rẹ̀:

11 Dafidi ọba si fi wọn fun Oluwa, pẹlu fadaka, ati wura ti o ti yà si mimọ́, eyi ti o ti gbà lọwọ awọn orilẹ-ède ti o ti ṣẹgun;

12 Lọwọ Siria ati lọwọ Moabu, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini, ati lọwọ Amaleki, ati ninu ikogun Hadadeseri ọmọ Rehobu ọba Soba.

13 Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia.

14 O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.

15 Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀.

16 Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe.

17 Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe.

18 Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8