2. Sam 4 YCE

Wọ́n pa Iṣiboṣẹti

1 NIGBATI ọmọ Saulu si gbọ́ pe Abneri kú ni Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ si rọ, gbogbo Israeli si rẹ̀wẹsi.

2 Ọmọ Saulu si ni ọkunrin meji ti iṣe olori ẹgbẹ ogun: a npe orukọ ọkan ni Baana, ati orukọ keji ni Rekabu, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti ti awọn ọmọ Benjamini: (nitoripe a si ka Beeroti pẹlu Benjamini:

3 Awọn ara Beeroti si ti sa lọ si Gittaimu, nwọn si ṣe atipo nibẹ titi o fi di ọjọ oni yi.)

4 Jonatani ọmọ Saulu si ti bi ọmọkunrin kan ti ẹsẹ rẹ̀ rọ. On si jẹ ọdun marun, nigbati ihìn de niti Saulu ati Jonatani lati Jesreeli wá, olutọ́ rẹ̀ si gbe e, o si sa lọ: o si ṣe, bi o si ti nyara lati sa lọ, on si ṣubu, o si ya arọ. Orukọ rẹ̀ a ma jẹ Mefiboṣeti.

5 Awọn ọmọ Rimmoni, ara Beeroti, Rekabu ati Baana si lọ, nwọn si wá si ile Iṣboṣeti li ọsangangan, on si dubulẹ lori ibusun kan li ọjọkanri.

6 Si wõ, nwọn si wá si arin ile na, nwọn si ṣe bi ẹnipe nwọn nfẹ mu alikama; nwọn si gun u labẹ inu: Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀ si sa lọ.

7 Nigbati nwọn wọ ile na lọ, on si dubulẹ lori ibusun rẹ̀ ninu iyẹwu rẹ̀, nwọn si lu u pa, nwọn si bẹ ẹ li ori, nwọn gbe ori rẹ̀, nwọn si fi gbogbo oru rìn ni pẹtẹlẹ na.

8 Nwọn si gbe ori Iṣboṣeti tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wi fun ọba pe, Wõ, ori Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọta rẹ, ti o ti nwá ẹmi rẹ kiri; Oluwa ti gbẹ̀san fun ọba oluwa mi loni lara Saulu ati lara iru-ọmọ rẹ̀.

9 Dafidi si da Rekabu ati Baana arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti lohùn, o si wi fun wọn pe, Bi Oluwa ti mbẹ, ẹniti o gbà ẹmi mi lọwọ gbogbo ipọnju,

10 Nigbati ẹnikan rò fun mi pe, Wõ, Saulu ti kú, li oju ara rẹ̀ on si jasi ẹni ti o mu ihin rere wá, emi si mu u, mo si pa a ni Siklagi, ẹniti o ṣebi on o ri nkan gbà nitori ihin rere rẹ̀.

11 Melomelo ni, nigbati awọn ikà enia pa olododo enia kan ni ile rẹ̀ lori ibusun rẹ̀? njẹ emi ha si le ṣe alaibere ẹjẹ rẹ̀ lọwọ nyin bi? ki emi si mu nyin kuro laiye?

12 Dafidi si fi aṣẹ fun awọn ọdọmọkunrin rẹ̀, nwọn si pa wọn, nwọn si ke ọwọ́ ati ẹṣẹ wọn, a si fi wọn ha lori igi ni Hebroni. Ṣugbọn nwọn mu ori Iṣboṣeti, nwọn si sin i ni iboji Abneri ni Hebroni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8