6 Ọmọdekunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi emi ti ṣe alabapade lori oke Gilboa, si wõ, Saulu fi ara tì ọkọ̀ rẹ̀, si wõ, kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan.
7 Nigbati o si yi oju wo ẹhin rẹ̀, ti o si ri mi, o pè mi, Emi si da a lohùn pe, Emi nĩ.
8 On si bi mi pe, Iwọ tani? Emi si da a lohùn pe, ara Amaleki li emi.
9 On si tun wi fun mi pe, Duro le mi, emi bẹ ọ ki o si pa mi: nitoriti wahala ba mi, ẹmi mi si wà sibẹ.
10 Emi si duro le e, mo si pa a, nitori ti o da mi loju pe, kò si tun le là mọ lẹhin igbati o ti ṣubu: emi si mu ade ti o wà li ori rẹ̀, ati ibọwọ ti o mbẹ li apa rẹ̀, emi si mu wọn wá ihinyi sọdọ oluwa mi.
11 Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mu, o si fà wọn ya, gbogbo awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀ si ṣe bẹ̃ gẹgẹ.
12 Nwọn si ṣọfọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbawẹ titi di aṣalẹ fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoripe nwọn ti ipa idà ṣubu.