27 Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀.
28 Lẹhin igbati Dafidi si gbọ́ ọ, o si wipe, emi ati ijọba mi si jẹ alaiṣẹ niwaju Oluwa titi lai ni ẹjẹ Abneri ọmọ Neri:
29 Jẹ ki o wà li ori Joabu, ati li ori gbogbo idile baba rẹ̀; ki a má si fẹ ẹni ti o li arùn isun, tabi adẹtẹ, tabi ẹni ti ntẹ̀ ọpá, tabi, ẹniti a o fi idà pa, tabi ẹniti o ṣe alaili onjẹ kù ni ile Joabu.
30 Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si pa Abneri, nitoripe on ti pa Asaheli arakunrin wọn ni Gibeoni li ogun.
31 Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀.
32 Nwọn si sin Abneri ni Hebroni: ọba si gbe ohùn rẹ̀ soke, o si sọkun ni iboji Abneri; gbogbo awọn enia na si sọkun.
33 Ọba si sọkun lori Abneri, o si wipe, Abneri iba ku iku aṣiwere?