1 GBOGBO ẹya Israeli si tọ̀ Dafidi wá ni Hebroni, nwọn si wipe, Wõ, egungun rẹ ati ẹran ara rẹ li awa iṣe.
2 Ati nigba atijọ, nigbati Saulu fi jọba lori wa, iwọ ni ẹniti ima ko Israeli jade, iwọ ni si ma mu wọn bọ̀ wá ile: Oluwa si wi fun ọ pe, Iwọ o bọ́ Israeli awọn enia mi, iwọ o si jẹ olori fun Israeli.
3 Gbogbo agba Israeli si tọ ọba wá ni Hebroni, Dafidi ọba si ba wọn ṣe adehun kan ni Hebroni, niwaju Oluwa: nwọn si fi ororo yan Dafidi li ọba Israeli.
4 Dafidi si jẹ ẹni ọgbọn ọdun nigbati o jọba; on si jọba li ogoji ọdun.